islamkingdomfacebook


YIYỌ SÀKÁ ATI IPA RERE TI O LE KO NIBI IRANRA ẸNI LỌWỌọ LAWUJỌ

YIYỌ SÀKÁ ATI IPA RERE TI O LE KO NIBI IRANRA ẸNI LỌWỌọ LAWUJỌ

4085
Eko ni soki
Dajudaju, ninu ohun ti o ga julo ti Olohun se ni oranyan ninu dukia ni zakah yiyo je, oun si ni eekete awon origun Islam, ati olukoworin irun ninu asokale Alukurani, niti paapaa, Olohun ti see ni ofin fun ogbon ti o dogongo, beeni, ko se ni ofin lati gba ninu dukia awon eru lasan, bikosepe, O je ohun isoo dukia won dii mimo, O si je iranlowo fun awon alaini won, ti yio maa je okunfa alekun ife laarin won, niti ifowosowopo ati amojuto ti ibasepo laarin mutunmuwa ni awujo.

(ASSAKATAU WADAORUHA FITTAKAFULULI IJITIMọHIYYI)

Awon erongba khutuba

1.         Alaye nipa jijẹ dandan yiyọ saka ati alaye awọn owó ti a maa nyọ saka rẹ.

2.         Ipa rere ti yiyọ saka yoo ko fun eniyan kọọkan ati awujọ

3.         Isẹrubani nipa kikọ yiyọ saka

4.         Alaye idajọ òranyàn saka

Akoko khutuba: isẹju marundinlogoji

 Ogun isẹju

الحمد لله رب العالمين جعل في أموال  الأغنياء حقا  للفقراء والمساكين وللمصارف التى بها صلّاح الدنيا والدين , وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له  ولا نعبد إلا إياه  مخلصين  موحّدين , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله الصادق الأمين صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه والتابعين لهم بإحسان إلى يوم الدين وسلم تسليما كثيرا. ...

Ọpe ni fun Ọlọhun, Ọba adẹda, ọba ti o sọ ninu tira Rẹ pe … ẹ na ninu ohun ti O fi yin se arole rẹ” Mo jẹri pe ko si ẹlomiran ti isin ododo yẹ, ayafi Ọlọhun nikan, ọba ti ko lorogun, bẹẹni mo si gbagbọ lododo pe Annọbi wa Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ Rẹ si ni, O sọ pe: “Bi mo ba fi ohun ti o to oke Hudu ni owo goolu ko ni dun mọmi ninu, ki ọjọ mẹta re kọja, ki owo naa wa wa pẹlu mi, ayafi eyiti mo ba fẹẹ na sidi ẹsin Ọlọhun loku”. Ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa baa ati ara ile rẹ ati awọn Sahaba rẹ, ati gbogbo ẹniti o ba fi daada tẹle wọn, titi di ọjọ ẹsan.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ọrọ wa ti oni yii o da lori ohun ti o maa njẹ ki arisiki eniyan ko lékún sii, ti yoo si jẹ ki ọwọ re dàgbà sòkè si, ti yoo si fọọ mọ, àní ti ibukun Ọlọhun yoo fi jẹ ti eniti nyọ ọ, ati  ohun ini rẹ. Ohun ti a nfọn rere rẹ ni saka, to jẹ ijọsin ti a maa nfi owoo se, eyiti Ọlọhun se ni òranyàn lori awọn ẹru Rẹ. Ẹ bẹru Ọlọhun ki ẹ si yọ saka ti Ọlọhun se ni òranyàn leyin lori, latiyọ ninu awọn owo yin, ti Ọlọhun pese fun yin. Ọlọhun mun yin jade lati inu iya yin, lẹniti ko mọ ohun Kankan , ti ẹ ko si ni agbára kankan lati se ẹmi ara yin ni anfani tabi lati ko ipalara báà. Lẹhinna Ọlọhun rọ arisiki fun yin, o si pese ohun ti ẹ ko lèrò fun yin, torinaa, ẹ yára dupẹ fun Un, ki ẹ si yọ saka to se lòranyàn fun yin, ki ọrun yin le mọ, ki ẹ si fi safọmọ owo yin. Bakannaa, ẹ sọra fun sisahun owó, toripe okunfa iparun, ati iyọ alubarika kuro ninu owo ni. Origun kẹta ni saka jẹ ninu awọn origun ẹsin isilaamu. O si jẹ òranyàn fun gbogbo musulumi to jẹ ọmọluabi, to bàlágà, to ni laakaye, to si ni owo to to odiwọn ti saka wọ. Ọlọhun sọ pe:

{ وَأَقِيمُواْ الصَّلاَةَ وَآتُواْ الزَّكَاةَ وَارْكَعُواْ مَعَ الرَّاكِعِينَ }

"Ẹ maa kirun dede, ki ẹ si maa yan saka, ki ẹ si maa tẹ pẹlu awọn ti ntẹ (ninu irun)” Suratul Bakọrah: 43.

Ọlọhun tun sọ pe:

"وَأَقِيمُوا الصَّلاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَمَا تُقَدِّمُوا لأَنْفُسِكُم مِنْ خَيْرٍ تَجِدُوهُ عِنْدَ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِير".

“Ẹ maa kirun ni akoko ki ẹ si maa mu saka wa”. Suratul Bakorah: 110.

Ọlọhun darukọ saka ati irun pọ nigba to le ni ọgọrin. Ninu adisi Abudullọhi bun Umar Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Wọn mọ isilaamu lori òpó marun un; mimọ Ọlọhun lọkan, ati gbigbe irun duro ati yiyọ saka, gbígba awẹ rọmọdana ati sise haji. Musilimu lo gba wa. Ọlọhun ti se ileri ìyà iná fun ẹniti o ba sahun pẹlu owó rẹ, ti o si kọ lati yọ saka. Ọlọhun sọ pe:

"وَلا يَحْسَبَنَّ الَّذِينَ يَبْخَلُونَ بِمَا آتَاهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ هُوَ خَيْراً لَهُمْ بَلْ هُوَ شَرٌّ لَهُمْ سَيُطَوَّقُونَ مَا بَخِلُوا بِهِ يَوْمَ الْقِيَامَة وَلِلَّهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِير".

“Ki awọn ẹniti nwọn nse ahun nipa ohun ti Ọlọhun  fun wọn ninu ọla Rẹ ma se ro pe oore ni o jẹ fun awọn, ọrọ ko jẹ bẹẹ, aburu ni fun wọn, laipẹ, a o fi ohun ti nwọn nse ahun rẹ ko wọn lọrun ni ọjọ ajinde. Ti Ọlọhun ni ogun sanma ati ilẹ ise, Ọlọhun ni Alamọtan nipa ohun ti ẹ nse” Suratul Al-Imran: 180.

Ojisẹ sọ pe itumọ ayah alakọkọ ni pe: Ẹniti a ba fun lowo, ti ko si yọ saka ori rẹ, wọn yoo sọ di ejò, ti o pọ loró, ti o jẹ ki o pari, ti yoo si we mọọ lára, ti yoo gba ẹbati rẹ mu, yoo maa saa jẹ, yoo si maa sọ pe: Emi ni owó rẹ, Emi ni pẹpẹ ọrọ rẹ,” Buhari lo gbaa wa.

Ẹyin musulumi, orisirisi awọn anfaani ni saka yoo se fun wa ninu ẹsin, ninu rẹ ni:

1.         Yiyọ saka jẹ ìpé origun kan ninu origun ẹsin Isilaamu, to se pe ninu rẹ ni oriire ẹda laye ati lọrun wa.

2.         O nmu ẹrú sunmọ Ọlọhun rẹ, ti yoo si mun lẹkun ninu igbagbọ rẹ.

3.         Ẹsan pupọ ni o sodo sibi yiyọ saka, Ọlọhun sọ pe:

"يَمْحَقُ اللَّهُ الرِّبا وَيُرْبِي الصَّدَقَاتِ وَاللَّهُ لا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيم".

"Ọlọhun yoo maa dín èlé kú yoo si ma bù si itọrẹ anu”. Suratul Bakọrah 276. Ọlọhun sọ eleyi ninu Suratul Romu: 39.

 Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Ẹniti o ba fi ohun ti o se deede dabidun se saara ninu ohun ti o kojọ lati ibi ohun ti o mọ ti Ọlọhun ko si ni ni tẹwọ gba nkankan, ayafi ohunti o ba mọ, Ọlọhun yoo gba owo naa pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lehinnaa yoo maa ree fun, ẹniti o fi se saara, gẹge bi ẹnikọọkan yin se ma ntọju ọmọ ẹsin rẹ titi ti yoo fi dabi òké”.

Buhari ati Musilimu lo gba a wa.

4.         Ọlọhun yoo fi pa awọn ẹsẹ oni tọhun rẹ. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Saka tabi itọrẹ aanu ti eniyan ba se maa npa ẹsẹ rẹ, gẹgẹ bi omi se ma npa iná”.

Ninu rẹ ni anfaani ti ìwà rere

1.         Yoo mu oluyọ saka wọ ijọ awọn ọlọrẹ.

2.         Yoo sọ orukọ di alaanu onikẹ awọn ọmọ iya rẹ ti ko ni .

Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Awọn ti wọn laanu ọmọnikeji wọn, Ọlọhun yoo laanu tiwọn naa”.

4.         Nina owó ati ẹmi fun awọn musulumi maa nfa isipaya ẹmi ti onitọhun yoo fi di ẹniti awọn eniyan yoo maa nifẹ si, niwọnba bi o se nna owo o si.

5.         Yiyọ saka naa ntunni niwa se ti ẹniti nyọọ yoo di ẹnimimọ kuro ninu awọn iwa ti kó dàra, Ọlọhun sọ pe:

"خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيْهِمْ إِنَّ صَلاَتَكَ سَكَنٌ لَّهُمْ وَاللّهُ سَمِيعٌ عَلِيم".

"Gba itọre aanu ninu ọrọ ki o fọ wọn mọ, ati ki o si fi sọ wọn di mimọ”. Suratul Taobat: 103.

 

Bakanna ni o tun ni anfaani ti awujọ

1.         Bíbíyá bukaata awọn alaini to se pe awọn ni wọn pọju lọ nilu.

2.         Ìbu agbara kun agbara mussulumi ati gbigbe wọn ga nipo ati ìsesí, idi niyi to fi jẹ pe ikan ninu awọn ọna ti a nna saka si ni jija gun si oju ọna Ọlọhun.

3.         O ma nle iwa kèéta, ilara kuro lọkan awọn alaini, toripe bi wọn ba nri olowo to ngbadun pẹlu owo rẹ to njẹ ohunti o wu, ti o nwọ asọ ti o dara pari, bata ati ọkọ ayọkẹlẹ to wàyàmí, ti nkan kan ko si kan sii lẹnu ninu ọla rẹ, o see se ki wọn gbin ikorira rẹ sọkan, toripe ko bawọn biya bukata kankan, sugbọn bi olowo bá ná diẹ fun wọn ninu owo rẹ, wọn yoo nifẹ rẹ bi oju, wọn ko si nii fẹ ki aburu Kankan sẹlẹ sii

4.         O maa n jẹ ki owo gberu sii. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe saka yiyọ kii jẹ ki owo dinku. O le din ni onka sugbọn ibukun ara owo naa ko ni gbẹ lailai.

5.         O maa nfa igbooro ati igbaaye fun owo ti a yọ saka rẹ, toripe bi wọn ba yọọ fun awọn kan, owo ti de ọdọ tiwọn na nuu, ko ni jẹ pe ọwọ awọn ọlọla ọlọrọ nikan ni yoo maa wa.

6.         Gbogbo awọn anfani wọnyi ati omiran naa ntọka si bi yiyọ saka se Pataki pupọ lati fi tun eniyan kọọkan ati awujọ se. Mimọ ni fun Ọlọhun ọba ojogbọn julọ.

Musulumi to jẹ ọlọrọ gbọdọ ri owo rẹ gẹge bi nka afipamọ ti Ọlọhun ko pamọ sii lọwọ, ti o si gbọdọ maa yọ ẹtọ rẹ fun awọn alainii, ti yoo si maa loo si ojupọna ti Ọlọhun yọnu si. Ọlọhun pilẹ ti se musulumi loju ọyin sibi ninawo fi biiya bukuta awọn alaini. Ọlọhun sọ pe:

{ مَّن ذَا الَّذِي يُقْرِضُ اللَّهَ قَرْضاً حَسَناً فَيُضَاعِفَهُ لَهُ أَضْعَافاً كَثِيرَةً وَاللَّهُ يَقْبِضُ وَيَبْسُطُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ}.

“Tani ẹniti yoo wín Ọlọhun ni ọrọ ni winwin ti o dara. On Ọlọhun  yoo di adipele fun un, ni adipele pupọ Ọlọhun A maa ko o ro, A si ma tẹ ẹ silẹ (fun ẹniti o wuu) ọdọ Rẹ ni a o si da nyin pada si". Suratul Bakọrah: 245.

Ilana yiyọ saka ti ẹlẹsin isilaamu ni ilana akọkọ ti ọmọniyan tii mọ, t  n se afimulẹ isamojuto, isakolekan awọn alaini, ti wọn nbukaata, ati nipa iwa pinpin dọgba tawujọ, laarin awọn to lẹran jọbọjọbọ labiya ti wọn le bawọn dasa mo ki ọ ki ọ.

Atipe yiyọ saka tun maa njẹ ki ibasepo awujọ tun le danhin si ni didawọ jọ le osi wọgbẹ, osi to jẹ isoro nla ninu awọn isoro awujọ ọrọ aje ati ti iwa.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹ lọọ mọ pe saka jẹ òranyàn ninu awọn owo kan ti Ọlọhun sa lẹsa.

1.         Owo goolu ati fadaka, pẹlu majẹmu ki goolu ati fadaka eniyan ti to odiwọn ti o yẹ, ti a o si yọ idarin ìdawàá ti o tumo si idakan ninu ogoji.

2.         Ùrúdù tijarati, ti o tumọ si: Gbogbo ohun ti a pa lese fun tita: lọkọ, ẹran-ọsin asọ ati awọn ohunti o yatọ sii ninu awọn dukia. Eyi to jẹ òranyàn ti a o yọ jade jẹ idarin idawaa, Nibẹrẹ ọdun kọọkan ni yoo ko gbogbo rẹ jọ ti yoo mọye to ba jẹ, ti yoo yọ odiwọn ti a wi siwaju. Yálà o kere siye ti o raja naa tabi o lekun tabi o se wẹku rẹ. sugbọn ohunti a ba pese silẹ fun ìló ara ẹni, saka ko wọnu rẹ o, bii ọkọ tabi ile ti eniyan ngbe tabi ti o gbaniyan si.

Ojise Ọlọhun sọ pe: saka ko jẹ dandan leeyan lori nibi ẹru rẹ ati ẹsin rẹ”. Ahmọdu ati ibnu Mọjaha lo gbaa wa.

Ẹyin musulumi, Ọlọhun ti salaye awọn ti wọn lẹtọ si gbigba saka; Ọlọhun sọ pe: “ọrẹ (saka) wa fun awọn talika ati awọn alaini ati awọn ti nsisẹ rẹ, ati awọn ti ọkan wọn fẹ gba (Isilaamu) ati fun irapada awọn ẹru, ati awọn ti o jẹ gbese ati si oju ọna Ọlọhun ati ọmọ ojuọna, òranyàn ni lati ọdọ Ọlọhun, Ọlọhun ni olumọ ọlọgbọn) suratul Taobat: 60.

Alaye lori awọn mẹjẹẹjọ

1.         Talaka ni awọn ti wọn kori tayọ diẹ ti ko to idaji ninu ohunti yoo to wọn ọn na. Bi eniyan ba jẹ eniti o ri ilaji ohun ti  yoo too naa ati ilaji ohun ti yoo to awọn ti o mbọ, iru ẹni bẹẹ alaini ni wọn yoo fun ni, ohunti yoo to oun ati awọn to n bọ ni odun kan.

2.         Alaini ni ninu ohunti yoo too na pẹlu awọn ti o nbọ, wọn yoo fun un ni ohunti o ba kù ti yoo fi to wọn.

3.         Awọn to nsisẹ rẹ: Ni awọn ti alasẹ ba yan lati lọọ mọọ gbaa wa lọwọ awọn olowo, ti wọn yoo tọju owo naa, leyinaa ti wọn o si ha fun awọn ti wọn lẹtọ sii. Wọn yoo fun wọn ninu saka ni ibamu si bi wọn se sisẹ si.

4.         Awọn ti ọkan wọn fẹ gba (Isilaamu): Ni awọn ti wọn jẹ olori ninu mọlebi awọn to se pe igbagbọ wọn ko lokun ninu, wọn yoo fun wọn ninu saka, ki imani wọn le lagbara sii, ki wọn le di olupepe lọ si inu isilaamu, ki wọn le jẹ awokọse rere fun awọn eniyan an wọn.  ti a bari  ẹnikan ti imani rẹ lẹ, sugbọn ti kii se olori, njẹ a le fun oun naa bi? awọn kan ninu awọn afa sọ pe: A lee fun un ni saka, toripe anfani ẹsin loore ju anfani tara lasan lọ, ti o ba jẹ alaini, wọn yoo fun un, lati le maa fi fun are rẹ lonjẹ jẹ, toripe fifun ọkan rẹ lonjẹ jẹ lo se pataki julọ.

5.         Awọn to jẹ gbèsè: Awọn ti wọn jẹ gbese sọrun, ti wọn ko si ri ọna ti wọn yoo gba fi san an

Awọn wonyi, wọn yoo fun wọn lati fi san gbese naa, o kere ni, tabi o pọ, kódà ko jẹ ọlọrọ labala onjẹ. Ko baa se baba tabi ọmọ ni ẹniti o jẹ gbese sọrun, awọn afa kan ni ki o yọ on fun un.

6.         Oju ọna Ọlọhun: Jijagun soju ọna Ọlọhun. wọn yoo fun awọn jagunjagun ni odiwọn ti yoo to wọn ọn na jagun, wọn yoo si ra nkan ijagun ninu rẹ, lara rẹ naa ni ọmọ ti o nkẹkọ ọrọ Ọlọhun. wọn yoo fun un ni odiwọn ti o to lati wa ima naa. Ayafi to ba ni owo lọwọ to le to o.

7.         Ọmọ oju ọna: ohun ni arinrinajo ti ko ri ohun ti yoo na, nibi irinajo, wọn yoo fun un ni odiwọn owo ti yoo gbee delu rẹ.

Ni ipari ẹ bẹru Ọlọhun , ẹ si maa se isiro isẹ ara yin, ẹ ma si lero pe saka ti Ọlọhun  ni ki a san jẹ òfò, bi ko se pe, origun kan ni ninu origun ẹsin isilaamu. Ọlọhun sọ pe:

{ياأَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ أَنْفِقُواْ مِن طَيِّبَاتِ مَا كَسَبْتُمْ وَمِمَّآ أَخْرَجْنَا لَكُم مِّنَ الأَرْضِ وَلاَ

تَيَمَّمُواْ الْخَبِيثَ مِنْهُ تُنْفِقُونَ وَلَسْتُمْ بِآخِذِيهِ إِلاَّ أَن تُغْمِضُواْ فِيهِ وَاعْلَمُواْ أَنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ حَمِيدٌ }.

"Ẹnyin ti ẹ gbagbọ, ẹ maa na ohun ti o dara ninu eyiti ẹ se nisẹ ati ninu ohun ti a mu jade fun nyin lati inu ilẹ, e ma se ronu kan eyiti kódàra ninu rẹ lati fi tọre, bẹni ẹnyin na ko jẹ gba a afi ki ẹ (mọmọ) mojukuro ninu rẹ, ki ẹ si mọ dajudaju pe Ọlọhun  ni ọlọrọ olutoyin”. Suratul Bakorah: 267.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹ fi ibẹru Ọlọhun tẹlẹ ati leke ohun ti ẹ ba n se, ẹ yọ saka owo yin, ki ẹ ko fun awọn ti o ba yẹ ni ibamu si orọ Ọlọhun ati ilana ojisẹ Rẹ. A n bẹ Ọlọhun ki o fi awa ati ẹyin se kongẹ ire Rẹ.

فاتقوا الله-  عباد الله-  في أمور دينكم عامة وفي زكاة أموالكم خاصة,  وليكن إخراجها  وصرفها  وسائر عباداتكم على مقتضى  كتاب الله وسنة ورسوله صلّى الله عليه وسلم  نسأل الله أن يوفقنا وإياكم لما يحبه ويرضاه , وأن يشملنا بعفوه  ومغفرته وصلّ اللهم على نبيك محمد  صلّى الله عليه وسلم وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر  وعمر وعثمان  وعلي وعن سائر أصحاب نبيك وعنا مهم برحمتك يأرحم الراحمين.