islamkingdomfacebook


ỌJỌ JIMỌH ATI IDAJỌ RẸ

ỌJỌ JIMỌH ATI IDAJỌ RẸ

3925
Eko ni soki
Ojo jimoh je ojo ti o loore julo ninu ojo ti oorun nran nibe, ojo yii ni Olohun daa anabi Adamo, ojo yi si ni asiko igbende yio sele, o je ojo odun fun awon musulumi, lati idi eyi ni a se se awon alaamori kan lofin nibe, lara re ni; khutubah jimoh, iwe ati ifin lofinda oloorun didun sara, ati wiwo aso ti o rewa julo lo kii ati irisi ti o pe julo ati imaagbe oruko Olohun tobi nigbati a ba nlo kii, ati isunmo imaamu, ati ipa okan po lati gbo waasi ati irannileti.

 

Awọn erongba lori khutubah na:

1.         Alaye ọla Ọlọhun ti o gbe awọn kan gan ninu awọn ohun ti o da

2.         Alaye ọla ọjọ Jimọh ati bi Ọlọhun se fi mọ ijọ Annabi Muhammad r.

3.         Alaye awọn idajọ irun Jimọh ati awọn miran ninu ẹkọ rẹ.

4.         Alaye ẹsẹ ti o wa fun ẹni ti o ba gbe irun Jimọh ju silẹ laiki.

 

أيها الناس اتقوا الله تعالى واعلموا أن يخلق ما يشاء ويختار: (وربك يخلق ما يشاء ويختار ما كان لهم الخيرة) الآية .

وأن لله تعالى الحكمة البالغة فيما يصطفي من خلقه فالله تعالى يصطفي من الملائكة رسلا ومن الناس : (الله يصطفي من الملائكة رسلا ومن الناس) الآية.

وفضل الله تعالى مكة على سائر البقاع، ثم من بعدها المدينة مهاجر خاتم الأنبياء.

ثم من بعدهما بيت المقدس مكان غالب الأنبياء الذين قص الله علينا نبأهم.

وفضل الله تعالى بعض الشهور والأيام والليالي على بعض فعدة الشهور عند الله اثنا عشر شهرا في كتاب الله يوم خلق السماوات والأرض منها أربعة حرم؛ وهي ذو القعدة وذو الحجة والمحرم ورجب الفرد.

وخير يوم طلعت فيه الشمس يوم الجمعة فعظموا رحمكم الله تعالى ما عظمه الله

Ọlọhun gbe ọla fun awọn ẹda rẹ kan lori omiran, ninu rẹ ni bi Mọkka se ni ipo ju awọn ile ti o ku lọ, bẹẹ naa ni Anabi Muhammad r laarin awọn Annabi  Ọlọhun ti o sẹku, osu Ramadan laarin awọn osu ti o sẹku, ọjọ Jimọh ni ọjọ ti o ni ọla julọ laarin awọn ọjọ mejeeje to wa laye.  Annabi Muhammad r  sọ wipe:

وعن أبي هريرة رضي الله عنه قال : قال رسول الله صلى الله عليه وسلم :  (خير يوم طلعت عليه الشمس يوم الجمعة؛ فيه خلق الله آدم، وفيه أدخل الجنة، وفيه أخرج منها) رواه مسلم وأبو داود والترمذي والنسائي.  

“Ọjọ Jimọh ni o loore julọ laarin awọn ọjọ ti o wa, ọjọ yii ni Ọlọhun se ẹda Annabi  Adam, ọjọ yii ni o wọ Aljanah, ọjọ yii na si ni o jade ninu rẹ.

 

Ninu awọn ohun ti a o se ti a o fi ri ọla ọjọ Jimọh jẹ, ni ki a se ohun ti Annabi Muhammad r  sọ ninu ọrọ rẹ pe:

عن عبد الله بن عمرو مرفوعا : ( من غسل واغتسل، ودنا وابتكر، واقترب واستمع، كان له بكل خطوة يخطوها قيام سنة وصيامها) رواه أحمد ورجاله رجال الصحيح.

"niti o ba wẹ ni ọjọ jimọh ti o si tete de jimọh, ti o si joko si aye ti o yẹ, ti o si tẹti gbọ khutubah, gbogbo ẹsẹ kọọkan ti o ba gbe yoo se dede sise Nafilah ati awẹ gbigba ọdun kan.( Ahmad lọ gba Hadith naa wa).

Ninu Hadith ti Musilimu gba wa Annabi Muhammad sọ wipe:

حذيفة رضي الله عنهما قالا قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : (أضل الله تبارك وتعالى عن الجمعة من كان قبلنا كان لليهود يوم السبت، والأحد للنصارى، فهم لنا تبع إلى يوم القيامة، نحن الآخرون من أهل الدنيا، والأولون يوم القيامة، المقضى لهم قبل الخلائق) مسلم.

 

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko fi ọjọ jimọh han awọn ti wọn saaju Annabi Muhammad rŽ; awọn Yẹhudi (Jews) mu ọjọ Satide, awọn Kirisitẹni mu ọjọ Sande, wọn yoo maa tẹle wa ni  titi di ọjọ Al-kiyamoh, awa ijọ Annabi  Muhammad r  ni a de ile aye kẹhin, sibẹ awa ni ẹni akọkọ ni ọjọ Al-kiyamoh,  ti wọn yoo si kọkọ se idajọ rẹ, ki wọn to se idajo awọn ẹda ti o sẹku.

Irun ọjọ jimọh pataki pupọ tori laada rẹ pọ, o si wa ninu awọn irun ti Isilaamu fun ni ipo atata.

Isilaamu fẹ ki Musulumi wẹ iwẹ ọranyan ni ọjọ Jimọh ki a si se imontoto daada, ki a si lo lọfinda oloorun (fun ọkunrin) ki a si wọ asọ ti o dara, ki a si tete de mọsalasi. Anabi Muhammad r sọ wipe:

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله قال: (من اغتسل يوم الجمعة غسل الجنابة ثم راح في الساعة الأولى فكأنما قرب بدنة) الحديث.

"ni ba wẹ ni ọjọ jimọh iru iwẹ ti a ma nwẹ fun janabah, ti o si tete de jimọh ni asiko akọkọ, o da gẹgẹ bi ẹni ti o fi rakunmi se saara."

A fẹ ki ẹni ba tete de si jimọh joko sunmọ Imam, ki o si bẹrẹ sii lo àkókò rẹ fun ijọsin bii kike Al-kur'an, sise Nafilah, sise afọmọ orukọ Ọlọhun, titi ti Imam yoo fi bẹrẹ khutubah, ti Imam ba ti bẹrẹ khutubah, yoo dakẹ jẹjẹ lati maa gbọ ọ. Ki iru ẹni bẹẹ ki jimọh naa pẹlu ibẹru Ọlọhun, ati ifarabalẹ, ki o si mo fi ọkan ba khutubah naa lọ. Ti wọn ba ki irun tan, ti o se awọn adhkaaru (Adua) ti a ma nse lẹhin irun, ki o se Nafilah Rakah mẹrin ninu masalsi, tabi ti oba ni idiwọ, ki o ki Nafilah meji ti o ba de ile, gẹgẹ bi Annabi  Muhammad r se ma nse ni igba aye rẹ. O sisọ pe:

قال : ((من توضأ فأحسن الوضوء ثم أتى الجمعة فاستمع وأنصت، غفر له ما بينه وبين الجمعة، وزيادة ثلاثة أيام)) رواه مسلم في صحيحه.

"ni ba se aluwala daradara, ti o si lọ si jimọh, ti o tẹti gbọ khutubah, Oluwa yoo se aforijin fun un laarin igba naa si akoko jimọh miiran ati ọjọ mẹta miiran: (Musilimu lo gba Hadith yii wa).

Ki musulumi jinna si gbogbo ohun ti o le mu un pa adanu awọn laada yii, bi pipẹ de si Jimọh, ki a ma tẹ ejika awọn ti wọn wa ki irun mọlẹ, Annabi  Muhammad r kọ fun ẹni ti o se eleyii ni igba aye rẹ. Sisọ ọrọ ni asiko Khutubah buru pupọ, kódà a kii ba ẹnikeji wa sọrọ pe ki o dakẹ

وروى الإمام أحمد عن علي قال: قال رسول الله : (من قال لصاحبه والإمام يخطب: صه، فقد لغا، ومن لغا فلا جمعة له).

"Ẹniti o ba sọ fun ẹni ti o wa lẹgbẹ rẹ pe dakẹ ni ọjọ jimọh ti Imam nse khutubah lọwọ ti se asise, ẹni ba se asise, ko ni irun Jimọh. (Hadith).

Ẹni ti o ba pa jimọh jẹ, jẹ ẹlẹsẹ ayafi iru ẹni ti o ba ni idiwọ nikan.

عن أبي قتادة رضي الله عنه أن رسول الله قال: (من ترك الجمعة ثلاث مرات من غير ضرورة طبع الله على قلبه).

"Ẹniti o ba fi Jimọh mẹta silẹ, ti kiise fun idiwọ kan, Ọlọhun yoo fi edidi di ọkan iru ẹni bẹ (Hadith).

 

 


Ninu awọn ohun ti Annabi Muhmmad r ma nse ni ọjọ jimọh ni wipe:  o ma nke Suratul Sajdah (Q: 32) ati Suratul Insaan (Q: 76) ni irun Subhi (Asuba) ọjọ jimọh. O si fẹ ki a pọ ni Asalaatu (itọrọ ikẹ) fun Oun ni ọjọ Jimọh ati oru rẹ (oru jimọh). Ọlọhun si ti pa wa lasẹ ki a tọrọ ikẹ fun un ninu Suratul Ahzab: 56

قال الله عز وجل: إِنَّ اللَّهَ وَمَلَائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِىّ ياأَيُّهَا الَّذِينَ ءامَنُواْ صَلُّواْ عَلَيْهِ وَسَلّمُواْ تَسْلِيمًا

 

"Dajudaju Ọlọhun ati awọn Mọlaika Rẹ ma nse ikẹ ati igẹ fun Annabi a pe ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ lododo ẹ tọrọ ikẹ ati igẹ fun un". Ninu Irun Jimọh Annabi ma nke lẹhin Suratul fatiha Suratul Jumuah (Q: 62) ati Suratul Munafikun (Q: 63) tabi ki o ke Suratul Aala (Q: 87) (Sabbih) ati Suratul Ghaasiyah (Q: 88).

 

Ninu awọn ọla jimọh ni ki a pọ ni adua sise ni ọjọ naa. Nitori pe asiko kan wa lọjọ yii- gẹgẹ bi Annabi Muhammad r  se sọ – ẹni ti Ọlọhun ba fi se kongẹ rẹ gbogbo ohun ti o ba bere lọwọ Ọlọhun ni yoo se fun un.

Oloriire eniyan ni ẹni ti o ba lo anfani nlanla yii, odikeji rẹ ni ẹni ti ko ba lo anfani yii. Ki Musulumi ri aridaju lati tẹle ọrọ ati isẹ Annabi ni ọjọ jimọh ati akoko miran naa. Ki Ọlọhun fi wa sinu awọn ti wọn yoo maa gba iwaju lati tẹle ọrọ Ọlọhun ati Annabi Muhammad r .  

هذا، قال الله تعالى : "إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون  "

اللَّهُمَّ لاَ تَدَعْ لَنَا فِي مَقَامِنَا هَذَا ذَنْبًا إِلاَّ غَفَرْتَه، وَلاَ دَيْناً إِلاَّ قَضَيْتَه، وَلاَ مَرِيضاً إِلاَّ شَفَيْتَه، وَلاَ مُسَافِراً إِلاَّ رَجَعْتَه وَلاَ ضَالاًّ إِلاَّ هَدَيْتَه وَلاَ دَاعِيًا فِي سَبِيلِكَ إِلاَّ  وَفَقْتَه، وَلاَ حَاجَةً مِنْ حَوَائِجِ الدُّنْيَا وَالآخِرَةِ هِيَ لَكَ فِيهَا رِضَا وَلَنَا فِيهَا صَلاَح إِلاَّ قَضَيْتَهَا وَيَسَّرْتَهَا لَنَا يَا رَبَّ الْعَالَمِين.

رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدا. رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِيَاِتنَا قُرَةً أَعْيُنٍ وَاجْعَلْنَا لِلَمُتَقِينَ إِمَامًا.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ.