islamkingdomfacebook


Irun ti A fin wa òjò (Salat al-Istisqaa

Irun ti A fin wa òjò (Salat al-Istisqaa

4490
Eko ni soki
Odaa je apere kan fun ijinna awon eniyan si itele ase Olohun, o si tun je itoka ti o han si ifagba Olohun oba ti ola re ga ya, iyapa Olohun je onfa aburu, o si maa npa alubarika re, ninu aanu Olohun lori awon eru re ni o se se irun iwa riro ojo ni ofin fun won, awon eru yio seri pada losi odo Oluwa won, won yio si wa iranlowo re lori rire aburu ti o sele si won danu, beeni ojo yio ba bere si maa ro, eleyi ti o je aanu si awon eru re.

Awọn Erongba Lori Khutubah Naa:

1- Alaye lori bi titẹle asẹ Ọlọhun se le jẹ okunfa rere fun ọlà ati árísìkí

2- Alaye lori pe eewọ ni iwa ẹsẹ si Ọlọhun (Allah).

3- Kikọ awọn eniyan ni ilana Annabi (Sunnah) nigbati ọda òjò ba de.

 

Khutuba Alakọkọ (fun ogún isẹju)

الحمد الله مغيث المستغيثين، ومجيب دعوة المضطرين، وكاشف الكرب عن المكروبين، ورافع البلاء عن المستغفرين، والصلاة والسلام على المبعوث رحمة للعالمين نبينا محمد وعلى آله وصحبه أجمعين. أما عباد

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun! Ibẹru Oluwa ni akori ọrọ ati ìse. Ati wipe anfaani pọ ti ọmọniyan yoo ri latari titẹle asẹ Ọlọhun U. Oluwa sọ bayi pe:

وَلَوْ أَنَّهُمْ أَقَامُوا التَّوْرَاةَ وَالْإِنْجِيلَ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْهِمْ مِنْ رَبِّهِمْ لَأَكَلُوا مِنْ فَوْقِهِمْ وَمِنْ تَحْتِ أَرْجُلِهِمْ مِنْهُمْ أُمَّةٌ مُقْتَصِدَةٌ وَكَثِيرٌ مِنْهُمْ سَاءَ مَا يَعْمَلُون [المائدة : 66]

"Iba se pe awọn (ẹni ti a fun ni tira siwaju) tẹ le ofin Taorata, Injila ati ohun (miran) ti a sọkalẹ fun wọn lati ọdọ Oluwa wọn ni, nse ni wọn o ba maa jẹhun lati oke wọn (nipasẹ òjò ti yoo rọ) ati lati abẹ ẹsẹ wọn (latari irugbin lorisirisi). Ijọ kan nbẹ ninu wọn ti o sisẹ (daada) niwọnba, sugbọn eyi ti o pọ ninu wọn ni isẹ ọwọ wọn buru" Oluwa tun sọ pe:

وَيَا قَوْمِ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ يُرْسِلِ السَّمَاءَ عَلَيْكُمْ مِدْرَارًا وَيَزِدْكُمْ قُوَّةً إِلَى قُوَّتِكُمْ وَلَا تَتَوَلَّوْا مُجْرِمِينَ  [هود : 52]

(Annabi Hud unaa jisẹ funa awọn eniyan rẹ bayi pe) Ẹyin eniyan mi, ẹwa aforijin ẹsẹ lọdọ Oluwa yin ki ẹ si tuuba (ronupiwada) lọ si ọdọ Rẹ. (Ti ẹ ba se bẹẹ) Oun yoo sọ  òjò kalẹ fun un yin lati sanmọ janti-rẹrẹ, yoo si se alekun agbara fun un yin, nitorinaa, ki ẹ ma se pehinda ni ti arufin".

Oluwa tun sọ pe:

وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْقُرَى آمَنُوا وَاتَّقَوْا لَفَتَحْنَا عَلَيْهِمْ بَرَكَاتٍ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ وَلَكِنْ كَذَّبُوا فَأَخَذْنَاهُمْ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُون [الأعراف : 96]

"Ti awọn ara ilu naa ba gba (Ọlọhun) gbọ ni ti wọn si payaa (Rẹ), A o ba si ilẹkun oore ati arisiki fun wọn ni oke ati ile. Sugbọn o wọn pee nirọ, ni A se gba wọn mu (pẹlu iya) nititori isẹ ọwọ wọn".

Ni idakeji ẹwẹ, iwa ẹsẹ a maa fa adanwo ati ori buruku, kódà a maa yọ alubarika kuro lara nkan. Idi ni yi ti ọkan ninu awọn asiwaju wa ti o ti rekọja lọ fi maa nsọ pe: "Ti n ba sẹ Ọlọhun ni ẹsẹ kan, emi a maa ri abọ rẹ latara iwa ti iyawo mi yoo hu si mi ati bi awọn nkan ọsin mi paapaa yoo se se simi lọjọnaa (ti wọn ko nii gbọ temi bi wọn ti maa n se tẹlẹ).

Alfa agba Ibn Al-Kọyyim (رحمه الله) sọ diẹ fun wa ninu awọn ohun aburu ti ẹsẹ dida maa n fa fun eniyan bii: iyẹpẹrẹ, aini oye ati laakaye to, aibikita nibi ti o ti yẹ ki ọmọluabi o tara, ailojuti, aarẹ ọkan, igbagbe iranti Ọlọhun, ki ikẹ Ọlọhun ti o ti wa pẹlu ẹlẹsẹ di afẹku, ki oju-inu eniyan fọ, ki eniyan di ẹni yẹyẹ, ki alubarika kuro lọdọ eniyan, ki araye maa bu ni, ki ẹmi aniyan ma balẹ ati ki eniyan jẹ kiki oroju lati jọsin fun Ọlọhun Ẹlẹda!

Ọda òjò jẹ ami kan pato ti a fi n mọ bawo ni awọn eniyan ti jinna si titẹle asẹ Oluwa to. Idi niyi ti Annabi Nuh u fi sọ fun awọn eniyan rẹ pe:

فَقُلْتُ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ إِنَّهُ كَانَ غَفَّارًا(10) . يُرْسِلِ السَّمَاءَ عَلَيْكُمْ مِدْرَارًا (11) وَيُمْدِدْكُمْ بِأَمْوَالٍ وَبَنِينَ وَيَجْعَلْ لَكُمْ جَنَّاتٍ وَيَجْعَلْ لَكُمْ أَنْهَارًا (12) مَا لَكُمْ لَا تَرْجُونَ لِلَّهِ وَقَارًا [نوح : 10 - 13]

"… Ẹ wa aforijin ẹsẹ lọdọ Oluwa yin, dajudaju Alaforijn lọpọlọpọ ni Oluwa. Kódà yoo rọ  òjò fuun yin lọpọlọpọ, yoo si fi owo ati ọmọ kẹẹ yin pelu, ti yoo si tun fun un yin ni awọn ọgba-oko tutu ati awọn ibu-odò. E e ti waa seyin ti ẹ fi nko iyán Ọlọhun kere bẹẹ (abi ẹ ko mọ Ẹni ti njẹ Oluwa ni)!

Gbogbo ohun ti o n sẹlẹ laye ode oni, bii ooru ati otutu lapọju, oju ọjọ ti o n yi pada, òjò ti ko rọ ni akoko rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, gbogbo rẹ ko sẹhin ohun ti ọmọniyan nfọwọọ fa latari iwa ẹsẹ. Oluwa ti Ọla rẹ ga kuku ti sọ asọọlẹ bayi pe:

ظَهَرَ الْفَسَادُ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِي النَّاسِ لِيُذِيقَهُمْ بَعْضَ الَّذِي عَمِلُوا لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُون [الروم : 41]

Alfa Saadu (Ajalu, arun, ọda- òjò ati bẹẹbẹẹ lọ.) yọ lori ilẹ ati ni ibudo, nititori afọwọfa ọmọniyan, ki Oun (Oluwa) le fun wọn tọwo diẹ ninu ẹsan isẹ wọn, boya wọn a le ronu-piwada".

Ni igba aye Ojisẹnla Muhammad r, Anas t sọ wipe bi iji ategun lile ba fẹ, awa a maa ri loju Annabi r (niti ibẹru ki o ma se pe iya Ọlohun ni o fẹẹ sokalẹ)" Imam Bukhari lo gbaa wa.

Ọna abayọ kan soso ni ki onikaluku wa o ronu piwada, ki a yẹ araa wa wo, nibo ni a ti kùna. Ẹnikọọkan mọ ohun ti o n wu ni iwa ẹsẹ, kódà bi ẹnikankan ko mọọ.

بَلِ الْإِنْسَانُ عَلَى نَفْسِهِ بَصِيرَةٌ (14) وَلَوْ أَلْقَى مَعَاذِيرَه [القيامة : 14 ، 15[

"Eniyan gan to ni ẹlẹri lori araa rẹ, bi o tilewu ki o maa wa awawi to"

Nitorinaa, ẹ jẹ ki a wi bi Annabi ti kọ wa pe:"Oluwa o! A nwa isọ pẹlu Ọlọhun kuro nibi aburu ẹmi araa wa ati kuro nibi awọn isẹ aburu ti a n se"

""نعوذ بالله من شرور أنفسنا و من سيئآت أعمالنا

Ninu hadiisi ti Zayd bin Khalid  al-Juhani t gba wa: o ni Ojisẹ Ọlọhun r ki irun Asunba fun wa ni aaye ti a n pe ni Hudaybiyyah lẹhin ti òjò ti rọ ni oru. Lẹhin ti wọn ti ki irun tan Annabi r kọju si awọn eniyan, o si sọ fun wọn pe: Njẹ ẹyin mọ ohun ti Oluwa yin sọ? Wọn daa lohun pe: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ (الله ورسوله أعلم). Annọbi r waa sọ pe: Ohun ti Oluwa yin wi nipe: Bi ilẹ ti mọ yi, apakn awọn ẹda ji saye ni olugba Ọlọhun gbọ, ti apakeji si ji ni alaigbagbọ! Ẹniyowu ti o ba sọ pe: Ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ ni  òjò fi rọ, iru ẹni bẹẹ ni o gba Ọlọhun gbọ ti o si se aigbagbọ si awọn irawọ. Sugbọn ẹniyowu ti o n wipe: irawọ bayi ni o mu ojo rọ, iru ẹni bẹẹ ni o se aigba Emi Ọlọhun gbọ ti o jẹ pe irawọ ni o gbagbọ. (Imam Bukhari lo gbaa wa).

أقول ما تسمعون، وأستغفر الله لي لكم فاتسغفروه وتوبوا إليه إنه هو التواب الرحيم.

 

            Khutuba Ẹlẹẹkeji (Isẹju mẹwa)

            Bi a ba se wa n tuba ẹsẹ ki a tun mọ pe ilana Annabi r ni lati ki irun Istisqaa'.

Ninu hadiisi ti Imam Bukhari gba wa, ojisẹ Ọlọhun r jade wa si aye ikirun naa ti o si kirun ti a fi n tọrọ ojo (Istiskọu). O daju kọ qiblah, o yi oju asọ ti o wọ pada, o si kirun rakaa meji pere. Abdullah bin Zayd t ni o see lalaye bẹẹ.

Ninu hadith miran Anas bin Malik t se alaye pe Annabi r a maa gbe ọwọ rẹ soke gaan lati se adua fi tọrọ ojo lọdọ Ọlọhun. Kódà kii gbe owo rẹ soke lálá bẹẹ nibi adua miran  yatọ si ti o  ba ntọrọ ojo. (Imam Bukhari lo gbaa wa bẹẹ).

O di ọwọ ẹyin Musulumi lọmọde ati lagba, lẹgbẹlẹgbẹ ati lọgba-lọgba,  ki ẹ tẹra mọ itẹle ti Ọlọhun I, ki ẹ maa gbe irun duro, ki ẹ maa yọ saka owo yin, ati ki ẹ  maa se dara-dara si awọn mọlẹbi yin.

Anas bin Malik t gba hadiisi wa lati ọdọ Annabi r o sọ pe: Ọlọhun Ọba ti O ga sọ bayi pe "Iwọ ọmọ Annabi Adamọ ti o n pe mi ti o si ni irankan pe maa da ọ lohun. Emi yoo fi ori ẹsẹ jin ọ, lai bikita bi iwọ ti jẹ ẹlẹsẹ ase –tunse to. Iwọ ọmọ Annabi Adamọ kódà bi ẹsẹ rẹ ba ga to sanmọ, ti iwọ si wa aforijin wa si ọdọ mi, Maa fi ori jin ọ. Iwọ ọmọ Annabi Adamọ, bi o ba wa ba Mi pẹlu ẹsẹ ti o fẹrẹ le kun gbogbo ilẹ, sugbọn ti iwo ko se ẹbọ pẹlu Mi (ti o ko jọsin fun nkan miran lẹhin mi), Emi yoo fi ori ẹsẹ jin ọ bi o ti to yẹn naa. (Imam Tirmidhi lo gbaa wa).

قال الحسن البصري: "أكثروا من الاستغفار فى بيوتكم، وعلى موائدكم، وفى طرقكم، وفى أسواقكم، وفى مجالسكم، وأينما كنتم فإنكم ما تدرون متى تنزل المغفر".

Ọkan lara awọn ẹni rere ti o ti siwaju (Salaf), Imam Al-Hasan al-Basri (رحمه الله) sọ bayi pe:  "Ẹ maa tọrọ aforijin lọpọlọpọ ninu awọn ile yin, lori tabili ounjẹ yin, ni awọn oju ọna ti ẹ n rin, ninu awọn ọja yin, ni aye ibujoko se faaji yin ati nibi gbogbo yowu ki ẹ le wa; nitoripe ẹyin ko mọ igbawo ni aforijin Ọlọhun le sọkalẹ".

اللَّهُمَّ أغِثْنَا، اللَّهُمَّ أغِثْنَا، اللَّهُمَّ أَغِثْنَا .اللَّهُمَّ اسقِنَا غَيثاً مُغيثاً، مَريئاً مريعاً نافعاً غير ضارٍّ ، عاجِلاً غيرَ آجِل. اللَّهُمَّ اسق عِبَادَكَ وبَهَائِمَك، وانشُرْ رحمتَكَ، واحي بَلدَكَ الميِّت. اللَّهُمَّ إِنَّهُ لَمْ يَنْزِل بَلَاء إِلَّا بِذَنْبٍ ، وَلَمْ يُكْشَف إِلَّا بِتَوْبَةٍ، وَهَذِهِ أَيْدِينَا إِلَيْك بِالذُّنُوبِ وَنَوَاصِينَا إِلَيْك بِالتَّوْبَةِ فَاسْقِنَا الْغَيْث.

اللهم أنت الله لا إله إلا أنتَ أنتَ الغني ونحن الفقراء إليك، أنزل علينا الغيث ولا تجعلنا من القانطين. اللهم أغث قلوبنا بالإيمان واليقين، وبلادَنا بالخيرات والأمطار يا رب العالمين. اللهم إنا خلق من خلقك، فلا تمنع عنا بذنوبنا فضلك.

اللهم إنا نستغفرك إنك كنت غفاراً، فأرسل السماء علينا مدراراً. اللهم أغثنا غيثاً مُغيثاً، هنيئاً مريئاً، نافعاً غير ضار، عاجلاً غير آجل. اللهم سقيا رحمةٍ لا سقيا عذابٍ ولا بلاءٍ، ولا هدمٍ ولا غرق.

وصلى الله وسلّم وبارك على نبينا محمدٍ وعلى آله وأصحابه أجمعين والتابعين ومن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدين.