islamkingdomfacebook


GBÍGBANI NÍ IYÀNJÚ LÓRÍ SÙÚRÙ SÍSE

GBÍGBANI NÍ IYÀNJÚ LÓRÍ SÙÚRÙ SÍSE

4139
Eko ni soki
Suuru koni wo ohunkohun ayafi ki o ko oso ba nkan naa, beeni, ko ni kuro nibi nkan ayafi ki o ko abuku baa nkan naa.Musulumi gbodo je onisuuru nibi iwuwasi re, koda tofi mo wiwa ijeemu wa, a ko gbodo wa owo ojiji. eleyii ni Olohun fi pawa lase imaa wa iranlowo pelu suuru ati irun kiki.

 

Erongba Lori Khutuba Naa:

1- Kikọni ni suuru sise, atipe bi o ti se jẹ iwa ti a gbọdọ ba lọwọọ Musulumi.

2- Alaye lori awọn ọna ti suuru sise pin si.

3- Suuru sise nii mu ki ibagbepọ laarin awujọ di irọrun.

الحمد لله رب العالمين على فضله وإحسانه، أمر بالصبر وأثنى على الصابرين ووعدهم أجرا عظيما؛ وأشهد أن لا إله الاّ الله وحده لا شريك له وكفى بالله عليما وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله صلى الله عليه وسلّم وعل آله وأصحابه وسلّم تسليما.

          Ọp ni fun Ọlhun, Ọba to da gbogbo da, lori la ati ik R lori enikọọkan wa. O pawa lase suuru sise, O si yin awn onisuru pupọ, bẹẹni O se adehun san to tobi fun wn. Mo jeri pe ko si nikan ti ijsin ododo tọ si ayafi Ọlhun nikan, Ọlhun Ọba  to ni Olumọ jul, bẹẹni mo jri pe Anabi  wa Muhammad rusin Ọlhun ni Ojis R si ni plu, Ik at Ig Ọlhun ki o maa ba, ati awn ara ile rẹ tofi dori awn sahabe r.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹ lọ mo pe suuru sise jẹ nkan pataki ti ko see fi oju yẹpẹrẹ.

Suuru sise ati aranse Ọlọhun jẹ ọmọ iya ti kii yaa araawn. Oluwa se adehun fun awn oni- suuru pe wn yoo yege. Bakkannaa ko si agbara ninu iroyin ẹni ti ko ni suuru. Oluwa wipe:

{يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا اصْبِرُوا وَصَابِرُوا وَرَابِطُوا وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُون}.

 "Ẹyin ti ẹ gbagbọ! Ẹ se suuru, koda ki suuru tiyin ju ti awọn ẹlomiran lọ, ẹ duro sinsin ki ẹ si bẹru Ọlọhun ki ẹ le se oriire… "Suratul Al-Imrana 3:200)

Ẹni ti o ba pofo suuru ti pofo igbagbọ ododo nitoripe Oluwa ni:

... فَإِنْ أَصَابَهُ خَيْرٌ اطْمَأَنَّ بِهِ وَإِنْ أَصَابَتْهُ فِتْنَةٌ انْقَلَبَ عَلَى وَجْهِهِ خَسِرَ الدُّنْيَا وَالْآخِرَةَ ذَلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ [الحج : 11]

"… ti nkan daadaa ba sẹlẹ si i (ọmọniyan), yoo dunnu yoo si fọkanbalẹ sii, amọ ti adanwo ba kan an, yoo pa ohun da, o (ẹni naa)  ti pofo aye ati ọrun, eyiun si ni ofo ti o foju han ".

Awọn ti wọn jẹ ẹni ifọkanbalẹ laye ni awọn oni-suuru bakanna awọn ni ẹniti igbesi aye wọn yoo rọrun.

Sugbọn  Oluwa wipe:

{ذَلِكَ فَضْلُ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَنْ يَشَاءُ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيم}.

"Oore Ọlọhun ni o, A si maa  fun ẹniti o ba wu U. Oluwa jẹ Ọlọla ti o tobi".

Suuru sise jẹ ikan ninu iwa musulumi, ẹnikan ko si nii gba iroyin pẹlu rẹ ayafi ẹniti oluwa ti jogun iduro sinsin fun. Awon ojisẹ Oluwa ati awọn iransẹ rẹ ni awọn ti wọn jẹ arikọse lori iwa suuru.

Imam Ahmad (ki oluwa kẹẹ) wipe: Oluwa darukọ suuru ni ọna aadọrun ninu Al-Kur’an. Ọla ti o pọ ni mbẹ fun suuru sise ati awọn oni suuru, lara eyi ni":

·        Oluwa se ẹyin fun awọn oni-suuru ninu Al-Qur’an bakanna O sise adehun pe ohun yoo san ẹsan wọn laini isiro. O wipe:

إِنَّمَا يُوَفَّى الصَّابِرُونَ أَجْرَهُمْ بِغَيْرِ حِسَابٍ [الزمر : 10]

·        Oluwa tun fun wa ni iro pe Oun nb plu wn, Oun yoo fi ọna m wn plu pe Oun yoo se aranse ti o ga fun wn.

·        Bakanna oluwa se suuru sise ni ọranyan awn asiwaju ki wn le ri is Oluwa j bi o titọ ati bi o ti y. Oluwa ni:

{وَجَعَلْنَا مِنْهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا لَمَّا صَبَرُوا وَكَانُوا بِآَيَاتِنَا يُوقِنُون}.

 "A se ninu wn ni asiwaju ti wn yoo ma tọ awn eniyan sọna, plu as Wa nigbati wn ni atmora (suuru), bakana ti wn si ni amdaju nipa awn ami Wa".

·        Oluwa se suuru sise ni ohun daradara fun ẹniyowu ti o ba fi se iwa wu.

·        Oluwa tun sọ ninu Al-Kur’an pe ẹni ti o ba ni suuru ati ipaya Rẹ papọ, ọwọ abi ète awon ọta ki yoo kaa bi o ti wulẹ ko mọ.

·        Ọlọhun ti so suuru ati aseyọri papọ ti wọn ko si le tuka.

·        Suuru sise ni ohun ti n ma n fa ki Ọlọhun nifẹ ẹru Rẹ daradara.

Ọlọhun wipe:"إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِين". "Dajudaju Ọlọhun nbẹ pẹlu awọn oni suuru".

·        Oluwa se adehun oriire mẹta fun awọn onisuuru ninu Al-kur’an pe:

{وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ (155) الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُمْ مُصِيبَةٌ قَالُوا إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعُونَ (156) أُولَئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ}.

"Fun awọn onisuuru ni iro idunnu. Awọn ti ma n sọ ti adanwo ba kan wọn pe ọdọ Oluwa ni ati wa, bẹẹ ọdọ Rẹ naa ni a o pada si. Awọn yẹn ni ikẹ ati igẹ oluwa yoo bo wọn daru bakannaa wọn yoo wa ninu ẹni imọna".

·        Oluwa ti se adehun Alujanna fun awọn onisuuru pe Oun yoo bọ okun ina kuro ni ọrun wọn.

·        Suuru sise je jíja ẹmi ara ẹni lógun kuro ni bi ibinu.

·        Suuru sise jẹ kikapa ahọn ẹni kuro nibi isọkusọ.

·        Suuru sise nii j ki ẹru kapa ara rẹ kuro nibi nina ara ẹni ati fifa asọ ya mọ ara ẹni lara ni igba ti adanwo ba de.

·        Ni kukuru, suru sise jẹ nini ifarada lori ohun-kohun ti o ba kan ọmọniyan ninu musiba.

Bakana ki a si mọ wipe Oluwa nikan ni a ma n keepe ni igba idra ati igba isoro. Nitoripe kikepe da Ọlọhun ni igba kuugba j ise aigbagbọ ninu Oluwa ati pe ni ti a tun n pe ko le dahun ibeere bi kii sepe yoo ma se alekun isoro ni.  Ọdọ oluwa ni a ma n gbe isoro lọ.

Suuru pin si ọna mẹta ọtọọtọ

Alakọkọ: Sise suuru lori awọn asẹ Oluwa lati le mu wa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

Ẹlẹẹkeji: Sise suuru kuro ni bi awọn nkan ti oluwa kọ fun wa.

Ẹlẹẹkẹta: Sise suuru lori awọn akọọlẹ oluwa lori gbogbo nkan pata.

Lori awọn nkan mẹtẹta yii ni Alfa Agba Sheik Abdul-Kọọdiri (Al-Jilani) ti wipe: ko si bi o ti wulẹ ki o ri, ru gbọdọ tẹ le asẹ Ọlọhun, jina si awọn eewọ Rẹ, ati ki o ni igbagbọ si kadara.

 

Bakanna ni Lukman sọ asọlẹ awọn nkan mẹta yii fun ọmọ rẹ pe: irẹ ọmọ mi, maa ki irun, maa pasẹ daadaa ki o si kọ iwa ibajẹ bakanna ki o ni atẹmọra lori ohun ti o ba kan ọ.

يَا بُنَيَّ أَقِمِ الصَّلَاةَ وَأْمُرْ بِالْمَعْرُوفِ وَانْهَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَاصْبِرْ عَلَى مَا أَصَابَكَ [لقمان : 17]

 

Musulumi ko gbọdọ maa tanmọ adanwo bakanna o gbọdọ maa se suuru lori ohun ti o ba baa ninu adanwo gẹgẹ bi o ti wa ninu Hadiisi Abdullah bn Abi Aofa.

Annabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa) ti kọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ lati maa rankan adanwo nitoripe ko si ẹni ti o mọ ninu wọn boya oun yoo le se suuru tabi yege nibi adanwo naa.

 

·        Oluwa ati Anaabi R gbawa niyanju lori pe ki a se suuru bakannaa ki a ma se kanju gg bi o ti wa ninu Hadiisi Khabaab ibn-l-Arati pe: Oluwa yoo dahun awn ibeere wa ni iwn igba ti a ko ba ti kanju.

·        Ọmọniyan ni lati maa se suuru titi di ọjọ iku bakannaa ki o yọnu si kadara lori gbogbo nkan.

·        Ẹniyowu ti adanwo ba sẹlẹ si, ti o si tẹ le asẹ Oluwa ti o pawa lasẹ suuru, Oluwa yoo fi Oun ti o dara ju ohun ti o gba ni ọwọ rẹ rọpo fun un. Eleyi wa ninu Hadiisi Ummu Sulamah.

·        Eniti Ọlọhun ba f yoo danwo plu orisirisi awn adanwo.

·        Adanwo jẹ nkan ti maa n pa ẹsẹ ọmọniyan ti o ba jẹ Musulumi rere r.

Abu Musa wipe: Anaabi (صلى الله عليه وسلم) sọ pe: ti ijọsin ba dinku fun ẹru kan nipa aisan abi irin ajo wọn yoo maa kọọ silẹ fun pe o tun se iru ijọsin ti o maa n se tẹlẹ.

Ni igbati aisan se Abu Bakari (ki Oluwa yọnu si) awọn eniyan kan lọ bẹẹ wo. Wn sọ fun un pe se ki a pe olùwòsàn (Dokita)? O dahun wipe: Olùwòsàn (tootọ tii se Ọlọhun Ọba) ti ri mi. Wọn bii lere pe ki ni o waa wi, Abubakri dahun pe: O sọ fun mi pe "Emi ni a se eyi to ba wuU".

Suuru sise lọdọ awọn ara ati alasunmo yoo maa kọdi awọn suta wọn si ọ.

Suuru ti ọkunrin ba se fun iyawo rẹ lori awọn asise r, Ọlọhun yoo maa fi laa kuro nibi aburu rẹ.

Bakanna suuru ti iyawo naa ba se lori awọn aburu ọwọ ọkọ rẹ ni yoo se sababi oriire rẹ.

Ọga gbọdọ se suuru fun awọn osisẹ ti n bẹ ni abẹ ẹ rẹ. Ko gbọdọ se bi o ti to, bẹẹni ki o maa ranti pe enikan ni o ko wọn si abẹ oun bakanna Ẹni naa si ga ju oun lọ

Ki Oluwa se itọnisọna emi ati ẹyin naa ki o ka wa mọ ara awọn ti yoo le maa se suuru bakanna ki o ma gbe ohun ti o le ju wa lọ kawa ni aya, ki o sise  wa ni ọmọ Alujannah.

فاتقوا الله عباد الله واصبروا على ما ينالكم فى هذه الدنيا من خير وشرّ فإنّ الإمامة فى الدين لا ينال إلاّ بالصّبر واليقين، اللهم اجعلنا عند البلاء من الصّابرين وعند النعماء من الشّاكرين. وصلّوا على الشّفيع المشفّع يوم الحساب فقد أمركم الله بذلك فى محكم الكتاب: {إنّ الله وملائكته يصلّون على النّبي يأيّها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما}.

Nitorinaa, ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin Musulumi, ki ẹ si se ifarada lori gbogbo ohun ti o ba n sẹlẹ siyin loore ati ni aida. Toripe onisuru nii jọba lawusa, suuru la fi n se asiwaju nidi ẹsin. A n tọrọ lọdọ Ọlọhun, ki O se wa ni eniti yio le se suuru nigbati adanwo ba de, ti yio si lee maa dupẹ lori oore Ọlọhun. Ẹ jẹ ka tọrọ ikẹ ati igẹ Ọlọhun fun Olusipẹ wa Anabi Muhammad gẹgẹ bi Ọlọhun se pasẹ rẹ ninu tira Rẹ pe : « Dajudaju Ọlọhun ati awọn Malaika Rẹ n fi ibukun fun Annabi, ẹyin ti ẹ gbagbo ni ododo, ẹ maa tọrọ ibukun fun un, ki ẹ si kii ni kiki alaafia ».