islamkingdomfacebook


NINU AWON ITUMO HAJJ ATI AWON ASIRI TI O WA NIBE

NINU AWON ITUMO HAJJ ATI AWON ASIRI TI O WA NIBE

4197
Eko ni soki
Nje enikan ri hajj ati bi o se tobi to, ati igbagbo ti o njo herehere, ati awon ogunlogo awon eniyan bi wonse wa ti won ngbe Olohun ga ti won sii ngbee tobi ti won sii nfi eyin fun, dajudaju, irisi hajji je ohun ti o seni leemo, o si je irisi ti o seni ni kayeefi, eleyiti awon muumini maa nyo pelu re, ti awon oluse olohunlokan si maa ndi eniiyi pelu re, ti o si maa nse awon olufonufora ni eemo, ti o ba je bee, kinni hajj tumo si fun yin eyin musulumi?

Awọn ero khutubah naa:

1.         Riran awọn eniyan leti isẹ Haji ati awọn ohun ti o ro papọ mọ.

2.         Riran awọn eniyan leti idẹra Isilaamu.

3.         Alaye Pataki ki a jọsin, Pataki ijọsin fun ẹnikọọkan ati apapọ awọn eniyan.

4.         Alaye wipe atunse gidi ko le sẹlẹ, ayafi pẹlu ẹsin ododo.

 

KHUTUBAH ALAKỌKỌ (OGUN ISẸJU)

أيها الناس، هل رأيتم الحج وضخامته، ورأيتم الإيمان وتوهجه، ورأيتم الجموع الغفيرة كيف أتت تعظم الله وتكبِّره وتحمده؟! لقد كان منظر الحج شيئًا عجيبًا ومنظرًا مَهولاً، ابتهج به المؤمنون، وعزَّ به الموحِّدون، وشَرِق به المجرمون، وانبهر به الغافلون. فماذا يعني لكم الحج يا مسلمون؟!

لا أظنّ أن تلك المشاهد العظيمة تمضي بلا اتعاظ، أو أن ذلك العدد الضخم يمر بلا اعتبار. لقد حضرت تلك الجموع الغفيرة تجيب دعوة الله لها، وحضرت تعظّم الله، وحضرت تعلن توحيدها لله رب العالمين

Ẹyin eniyan, ẹ o wa ri bi eniyan se ma n pọ to ni Mọkka lati jọsin fun Ọlọhun? Inu awọn Musulumi ma n dún pupọ, o si jẹ iyi fun awọn ti wọn mọ Ọlọhun lọkan soso Ki ni Haji tumọ si Ẹyin olugba Ọlọhun gbọ? Ọlọhun sọ wipe:

{وَلِلَّهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ البَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلاً}.

"Ọlọhun se Haji ni ọranyan fun awọn ti o ba ni agbara rẹ". (Surat Al-Imran).

Awọn eniyan ti o pọ ni wọn nda Ọlọhun lohun lọdọọdun. Dajudaju eleyi ntọka si titobi Ọlọhun Adẹda, o si ntọka si titobi Isilaamu yi. Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Haji jẹ ibupade apapọ fun awọn ọmọlẹyin Annabi Muhammad  r , ti yoo fun asepọ wọn lagbara ti wọn yoo si tibẹ mọ ara wọn, ti wọn yoo si maa se iranlọwọ fun ara wọn.

O ri mimọ Ọlọhun lọkan soso ni Ọlọhun gbe isẹ Haji le lori, imọ Ọlọhun lọkan ti o fi ran gbogbo awọn Annabi Ọlọhun rẹ, ti tori imọ Ọlọhun lọkan yi ni o  fi kọ ile naa ni Mọkka. Ọlọhun sọ wipe:

{وَإِذْ بَوَّأْنَا لإِبْراهِيمَ مَكَانَ الْبَيْتِ أَن لاَّ تُشْرِكْ بِى شَيْئًا وَطَهّرْ بَيْتِىَ لِلطَّائِفِينَ وَالْقَائِمِينَ وَالرُّكَّعِ السُّجُودِ}.

" Atipe nigbati A fi aye ilẹ na han Ibrahim, pe: Irẹ ko gbọdọ da nkankan pọ mọ Mi atipe ki o fọ ile Mi mọ fun awọn olurọkirika (a) ati awọn olugberunduro ati awọn olubẹrẹ oluforibalẹ" Haji: 26.

Mimọ Ọlọhun lọkan soso yi ni ohun ti Ọlọhun tori rẹ se ẹda ọmọ eniyan saye ti o si fi sẹ ran awọn Annabi rẹ. Gbogbo awọn ami ti o wa ninu ile nla yi ntọka si titobi Ọlọhun ati ijẹ ọkan soso Rẹ. Ki Musulumi le jinna si ẹbọ ati ìwá orogún pẹlu Ọlọhun ni o tun se sọ ninu Al-kur'an:

{ذلِكَ وَمَن يُعَظّمْ حُرُمَاتِ اللَّهِ فَهُوَ خَيْرٌ لَّهُ عِندَ رَبّهِ وَأُحِلَّتْ لَكُمُ الأنْعَامُ إِلاَّ مَا يُتْلَى عَلَيْكُمْ فَاجْتَنِبُواْ الرّجْسَ مِنَ الأوْثَانِ وَاجْتَنِبُواْ قَوْلَ الزُّورِ}.

"Eyi ni (jẹ bẹẹ): ẹni ti o ba se awọn ofin Ọlọhun ni pataki, eyi ni o dara fun lọdọ Ọlọhun rẹ, Atipe a se awọn ẹran ọsin ni ẹtọ fun nyin ayafi awọn ti a nka (ewo rẹ) fun yin, nitorinaa, ẹ jinna si ẹgbin orisa atipe ki ẹ jinna si ọrọ irọ" Haji: 30.

Ọlọhun se alaye bawo ni a se nse isẹ Haji ni ase pe, Annabi Muhammad r na si se alaye rẹ pẹlu, kódà oun na tun se isẹ Haji naa pẹlu. Ọlọhun si se ileri wipe:

وَاتَّقُواْ اللَّهَ وَاعْلَمُواْ أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ [البقرة:196

Iya Oun le pupọ fun ẹni ti o ba fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn isẹ Haji na."

Al-Baqọrah: 196.

Haji jẹ, akoko inawo ati ifọwọsowọpọ lati se isẹ oloore, o tun jẹ akoko lati ran ẹlomiran lọwọ, ti a si gbudọ se akolekan awọn ẹlomiran. Oluwa sọ wipe:

لّيَشْهَدُواْ مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُواْ اسْمَ اللَّهِ فِى أَيَّامٍ مَّعْلُومَاتٍ عَلَى مَا رَزَقَهُمْ مّن بَهِيمَةِ الأنْعَامِ فَكُلُواْ مِنْهَا وَأَطْعِمُواْ الْبَائِسَ الْفَقِيرَ [الحج:28

"Ki n wọn le ri rere awọn anfaani ti o wa fun, ati kin wọn le maa pe orukọ Ọlọhun ninu awọn ọjọ ti a mọ, lori awọn nkan ti o pa lese fun wọn ninu ẹran ọsin; nitorinaa, ẹ jẹ ninu wọn ki ẹ si fun ẹniti ara ni (ti o jẹ) talika jẹ" Haji: 28.

Ni ọpọlọpọ aye ti Ọlọhun ba nsọ nipa isẹ Haji ni inu Al-kur'an ni o ma ntẹnu mọ ipaya Ọlọhun.

وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيْرَ الزَّادِ التَّقْوَى وَاتَّقُونِ ياأُوْلِي الألْبَابِ [البقرة:197]

"Ki ẹsi pese dani, ese ti o dara ju ni ibẹru Ọlọhun; ki ẹ si bẹru Mi, ẹyin onilakaye" Al- Bakarah: 197, bakannaa ni Al-Bakarah: 196, Al- Bakarah: 203, Haji: 32 ati Haji: 37.

Akoko Haji jẹ asiko ti Musulumi gbogbo aye yoo pade lati dijọ jọsin fun Ọlọhun kan soso eleyi ni o sọ di dandan fun wọn lati jijọ se ara wọn lọkan, ki wọn si rira wọn gẹgẹ bi ara kan soso. Ko gbọdọ si motomoto lọkan ẹnikẹni; tori pe gbogbo wọn ni wọn wa ni iwaju Ọlọhun kan soso, bi o tilẹ jẹ wipe ilu onikaluku yatọ, ẹya wọn si yatọ ipo wọn lawujọ yatọ ede wọn yatọ, kódà asa wọn yatọ pẹlu. Oluwa sọ wipe:

إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عَندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ [الحجرات:13].

"Ẹni ti o ni apọnle julọ ninu yin ni ẹni ti o npaya Ọlọhun"

Al-Hujuraat: 13.

Haji jẹ apejọ gbogbo agbaye, ti o ntọka si ẹyọkan Isilaamu, ti gbogbo onikaluku yoo pade ni Arafah lati jọsin fun Ọlọhun kan soso, Ọlọhun tako ipin yẹlẹ -yẹlẹ Musulumi, kódà O ki ilọ fun wọn ki wọn ma se se iyapa ẹnu pẹlu.

Haji jẹ akoko lati sọ igbagbọ di ọtun, ki wọn si se atunse ẹmi pẹlu, Haji yoo kọ Musulumi ni amumọra, afarada ati ọpọlọpọ suuru, tori pe yoo jẹ iparẹ esẹ, yoo si jẹ laada fun wọn ni ọdọ Ọlọhun. Annabi Muhammad r sọ pe:

(من حج فلم يرفُث ولم يفسُق رجع من ذنوبه كيوم ولدته أمه) أخرجاه.

"Ẹni ba se Haji laise isekuse, ti ko si sọ isọkusọ, iru ẹni bẹẹ yo jade kuro ninu ẹsẹ rẹ gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ bi lọmọ" (Bukhari ati Musilimu).

< face="'Times New Roman', serif" class="Apple-style-span">

- ومن معاني الحج أنه ذكرى إلى الآخرة وتنبيه إلى ذلك اليوم الشديد، {رَبَّنَا إِنَّكَ جَامِعُ النَّاسِ لِيَوْمٍ لاَّ رَيْبَ فِيهِ}. فيوم عرفة صورة مصغرة لمحشر الناس يوم القيامة، وفية تذكير باجتماع الناس إلى ربهم وخضوعهم له، وقد أصابهم من الرهق والتعب ما أصابهم.

- ومن معاني الحج أنه مظهر فريد في التدين والعبادة، لم يؤتِ لأمة من الأمم، يدل على شرف هذه الأمة، وأنها الأمة الباقية الخالدة، فمهما أصابها من سموم وبليات إلا أنها باقية ما اتجهت إلى ربها وقصدت بيته وحرمته، فلماذا اليأس وهذا الحج يجدد الوصال؟! ولماذا الحزن وهذا الحج يوثق الرابطة ويزيد  في التآلف والمحبة؟!

Haji jẹ akoko iranni leti ọjọ Al-kiyamah ọjọ pamurẹkẹtẹ, ọjọ ti onikaluku yoo kojọ ni iwaju Ẹlẹda rẹ. Pipọ ati ipejọ awọn eniyan ni akoko yii nse itọka si ifarada ati amumọra, eyi ti ọmọ eniyan yoo pade eyi ti o tobi ju bẹẹ lọ ni ọjọ idajọ, ayafi ẹni ti o ba sin Ọlọhun pẹlu ọkan mimọ. Ẹni ba se Haji yoo ri apọnle ti Ọlọhun fi si inu Isilaamu yoo sise alabapade orisirisi ẹya, yoo si se alabapade awọn eniyan ti wọn jẹ eniyan ti o nfẹran sunnah Annabi Muhammad r .

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, oore ti o pọ nduro de ijọ Musulumi, Haji kọ Musulumi ni sise deede, bayi ni ifọkanbanlẹ ati oore ti o pọ se nkari ilu Musulumi.

Haji ni kii jẹ iyatọ wa laarin orilẹ ede ti o n lo ofin Ọlọhun ati eyi ti ko mọ Ọlọhun, Ifọkanbalẹ ti o wa ni Mọkka ati Mọdina han si gbogbo aye tori pe wọn nlo ofin Ọlọhun. Iyatọ wa laarin ẹni ti o ni ọlaju aye nikan sugbọn ti ko mọ nkankan nipa Adẹda Ọlọhun rẹ. Ko si ifọkanbalẹ kan ayafi ninu Isilaamu. Ti gbogbo ilu Musulumi aye ba le pada si lilo ofin Ọlọhun gẹgẹ bi ara Mọkka ati Mọdina se nlo alaafia ati irọrun yoo pada si gbogbo awujọ aye bakannaa.

O yẹ ki gbobgo Musulumi mu Kura'an ati Hadith lọwọ daradara ki wọn fi le se ọkan soso ki wọn si ma se pin yẹlẹ yẹlẹ, isọkan yi ni jẹ ibẹru fun awọn keferi. Ṣebi Kur'an kan soso ni a ni, sebi Ka'bah kan ni a jijọ nda oju kọ, sebi Annabi Muhammad r  ni Ọlọhun ran si gbogbo wa, sebi a ko ni ẹlomiran ti a n jọsin fun lẹhin Ọlọhun kan soso Allah…. Gbogbo eleyi ni ipade ọdọọdun ti a n pade ni Mọkka nkọ wa.

أيها المسلمون : هذا، واعلموا رحمني الله وإياكم أن الله جل جلاله أمرنا بالصلاة على نبيه وقال جل وعلا قولاً كريماً: إن الله وملائكته يصلون على النبي يا أيها الذين آمنوا صلوا عليه وسلموا تسليماً [الأحزاب:56].

اللهم إني أعوذ بك أن أشرك بك و أنا أعلم، و أستغفرك لما لا أعلم".  اللهم ارزقنا الإخلاص في القول والعمل.

اللّهُمَّ أَعِزَّ الإسْلاَمَ وَالْمُسْلِمِينَ، وَدَمِّر أَعَدَاءَكَ أَعَدَاءَ الدِّينِ، وَانْصُرْ عِبَادَكَ الْمُوَحِّدِينَ، اللّهُمَّ عَلَيْكَ بِالْكَفَرَةِ الْفَجَرَةِ فَإِنَّهُمْ لاَ يُعْجِزُونَكَ يَارَبَّ الْعَالَمِينَ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَدَابَ النَّارِ.