islamkingdomfacebook

ỌDUN ILEYA

ỌDUN ILEYA

5428
Eko ni soki
.Odun ileya je odun ifemijin, odun orenta ati aanu fun awon alaini ,odun ti ogunlogo awon musulumi ma nkora jo lati se eleyi ti o tobi julo ninu awon aami esin ti a mo si hajj. Ore toretore a maa han ni odun ileya lati ara pipa eran odun ati gungunran fun iwasumo Olohun ti ola re ga ati fifi tore fun awon alaini ati talaka.

 

Awọn erongba khutubah naa.

1-               Itumọ  ọdun ninu ede  ati agbe kalẹ  ẹsin.

2-               Ibamu ọdun si adamọ  ọmọ  eniyan.

3-              Itumọ ọdun gẹgẹ bi i idupẹ fun Ọlọhun  latari awọn idẹra Rẹ,  bii gbigbe  orukọ  Ọlọhun tobi ati irun kiki, sise  abẹwo ati pinpin ẹbun ọdun.

4-                 Alaye awọn idajọ ti o wa fun ọdun.

ọdun jẹ  ibamu si adamọ  ẹda eniyan , bakannaa  o  si njẹ  ọpẹ  fun Ọlọhun  Allah. Ọlọhun sọ  wipe :

"فطرة الله التي فطر الناس عليها لا تبديل لخلق الله".

“Adamọ  Ọlọhun  eyiti o da mọ  ẹda eniyan , ko  si ohun ti a le  fi paarọ  ẹda Ọlọhun ” Suratur ruum: 30

Ọdun tumọ  si nkan mẹrin; pipe jọ , aye  ti a o  pẹ jọ si, akoko  ti ipe jọ naa yoo jẹ  ati iru ijọsin ti a o se  ni akoko  ọdun. Oluwa ti Ọla Rẹ  ga sọ wipe  :

قال الله تعالى:"و لكل أمّةٍ جعلنا مَنْسَكا ليَذكروا اسم الله على ما رزقَهم من بهيمة الأنعام، فإلهكم إله واحد، فله أَسْلِموا، و بشِّرِ المخبتين".  سورة الحج :34

 “ Gbogbo  ijọ  kọọkan lo ni ijọsin, ki ẹ  (ẹyin musulumi) ranti Ọlọhun  latari awọn ẹran ti ẹ  o fi jọsin fun Ọlọhun , Ọlọhun  tiyin jẹ ẹyọkan soso  Ọlọhun yii ni ki ẹ  gba fun, ẹ fun awọn ti wọn rẹ  ara wọn nilẹ  fun Ọlọhun ni iro idunu.

 Anasi jẹ  ki a mọ wipe :

رواه أنس أن قدم النبي  المدينة، و لهم يومان يلعبون فيهما. فقال قد أبدلكم الله بهما خيرا منهما: يوم الأضحى، و يوم الفطر".

 

Nigba ti Annabi Muhammad (r) de  ilu Mẹdinah, awọn  ara ilu naa ni ọjọ meji ti wọn fi n nsere  , Annabi sọ  wipe : Ọlọhun  ti paarọ  ọjọ  mejeeji yii pẹlu eyi ti o dara juu lọ : ọjọ  ọdun ileya ati ọjọ  ọdun aawẹ .”

ọjọ  ọdun ileya jẹ ọjọ ọdun ti a maa n kirun fun Ọlọhun  Allah gẹgẹ  bi Ọlọhun  se  pa Annabi Rẹ  lasẹ  ninu Al-kur’an wipe :

"فصل لربك وانحر". 

“ Ki irun fun Ọlọhun  rẹ  ki o si pa ẹran ileya rẹ ”. suratul-kaothar.

قال ابن عمر:"الأضحية سنة"- أخرجه عبد الرزاق في المصنف قال الإمام الشعبي:"لم يكونوا يرخصون في ترك الأضحية إلا لحاج، أو مسافر". قال أبو أيوب الأنصاري،:"كان الرجل في عهد النبي  يضحي بالشاة عنه، و عن أهل بيته، فيأكلون، ويُطعمون. ثم تباهى الناس، فصار كما ترى"- أخرجه ابن

ماجه

Ibn Umar sọ wipe : ọdun ileya jẹ  Sunnah .Awọn alfa sọ wipe : Ko lẹtọ  lati fi ileya silẹ  ayafi fun ẹni ti o ba wa ni Haji  lo sẹku. A rigbọ  lati ọdọ  Sahabe  Agba yẹn : Abu Ayyub Al-ansari wipe : ni aye Annabi Muhammad (r) eniyan kan ma npa ẹran ileya kan fun ara rẹ   ati awọn ara ile rẹ , wọn yoo si jẹ  ninu rẹ , wọn yoo si fun ẹlomiran na jẹ  ninu rẹ , lẹhinaa ni awọn eniyan yoo si maa dunnu, ki o to wa dabi o seda loni! Ibn majah lo gba a wa.

Annabi pa asẹ  pe  ki a pin ẹran ileya si ọna mẹta, ninu ọrọ rẹ ti o sọ  wipe : ẹ jẹ  ninu rẹ , ki ẹ  si fi se saara ninu rẹ , ki ẹsi tun fi pamọ ninu rẹ.

ابن عباس قال: قال رسول الله:"ما من أيام أعظم عند الله، ولا أحب إليه العمل فيهن من أيام العشر، فأكثروا فيهن التسبيح، والتكبير، والتهليل"- أخرجه الطبراني في الكبير.

Ibn Abbas lo gbahadiisi miran  wa wipe : Ko  si ọjọ ti isẹ laada tobi ti o to  awọn ọjọ yi, torinaa ki ẹ  se  afọmọ  orukọ  Ọlọhun  nibẹ , ki ẹ  sigbe orukọ Rẹ  tobi nibẹ , ki ẹ si gbe o rukọ  Rẹ  ga nibẹ pẹlu” Tọbarani lo  yọ  Hadiisi yii jade .

 

 

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun , akoko  ọdun jẹ  ,akoko  ayọ , idunu ati abẹwo  si awọn ẹbi ati araa wa. Aisa (رضي الله عنها) sọ  wipe :                 

قالت عائشة-رضي الله عنها-:"كانت الحبشة يلعبون يوم عيد فدعاني رسول الله  فكنت أطلع من عاتقه فأنظر إليهم، فجاء أبو بكر فقال النبي  دعها، فإن لكل قوم عيدا، وهذا عيدنا"- أخرجه أحمد. و في رواية أخرى:"لتعلم اليهود أن في ديننا فسحة"- أخرجه أحمد.

“awọn ara Habasha nse ere ni ọjọ  ọdun, Annabi si fi mi kalẹ , lati maa woran wọn lẹgbẹ ejika rẹ, nigbati Abubakari de, (o fẹ  lati kọ fun Aisa) Annabi si sọ wipe : fi kalẹ ; gbogbo  ijọ  lo ni ọdun tirẹ , eleyi ni ọdun tiwa” Ahmad lo gba wa. Ninu ẹgbawa miran ti Ahmad tun gba wa . o ni Annabi sọ wipe : “  Ki awọn Yẹhudi lee  mọ wipe akoko  isinmi,   idunnu ati ere wa ninu ẹsin tiwa naa ”.

Orisirisi awọn ohun kotọ  kan ma nsẹlẹ ni akoko  ọdun o yẹ  ki awọn alfa pe akiyesi awọn eniyan si ibẹ , gẹgẹ  bi didapọ laarin ọkunrin ati obinrin, wiwọ  asọ  ti o fi ihooho  obinrin silẹ , kikọse  Yẹhudi ati Nọsọra gẹgẹ  bii sise  (CARNIVAL), ijo kijo , ilu kilu, iwọ kiwọ , irun kirun ni didi ati irun kirun ni gigẹ .. ati awọn iwa jakujaku miran ti Ọlọhun  ti ọla Rẹ  ga ko ni ifẹ  si, gbogbo  rẹ  ni ki a pe  akiye si awọn eniyan si  ki a si jẹ ki awọn olupaya Ọlọhun  naa rẹ  oju wọn nilẹ .

Alfa wa Saori  sọ wipe :

قال الإمام سفيان الثوري:"ينبغي للإنسان إذا كان يوم العيد أن يبدأ فيغض بصره، يهتم بذلك"- أخرجه وكيع في الزهد.

O yẹ  ki musulumi rẹ  oju rẹ  nilẹ ni akoko ọdun. Ki o si maa se  akolekan eleyi, a o  ri ọrọ  yii ninu tira Suhudu ti wakii”.

Annabi Muhammad (r) sọ  wipe :

 روى أبو هريرة عن النبي  يقول:"من حمل علينا السلاح فليس منا"- أخرجه ابن ماجه. وقال الإمام الحسن البصري:"نُهوا أن يحمِلوا السلاح يوم عيدٍ إلا أن يخافوا عدوا"- ذكره البخاري تعليقا.

“ẹni ti o ba gbe  ohun ija dani ni akoko ọdun ko nii si ninu ijọ wa ni ọjọ  Al-kiyamah” Bukhari  se  alaye  wipe  a kọ  ki agbe  ohun ija ni akoko  ọdun ayafi ti a ba mbẹru awọn ọta.

Ti ọjọ  ọdun ba se  deede  ọjọ  Jimọh, a le  ma ki Jimọh yẹn ti a ba ti ki irun yidi, sugbọn eleyi ko  tumọ  si wipe  a ko nii ki irun aila (Suhuri) ọjọ  yẹn . wọn ni Uswman bun ‘Afan ki irun yidi ti o papọ  mọ  Jimọh, lẹhin ti o ki irun tan o sise  khutubah o wa sọ  wipe :

قال أبو عبيد مولى ابن الأزهر: "شهدت العيد مع عثمان بن عفان، فكان ذلك يوم الجمعة فصلى قبل الخطبة ثم خطب، فقال: يا أيها الناس إن هذا يوم قد اجتمع لكم فيه عيدان، فمن أحب أن ينتظر الجمعة من أهل العوالي فلينتظر، ومن أحب أن يرجع فقد أذنت له"- أخرجه البخاري.

“ẹyin eniyan, oni yii jẹ  ọjọ  ti Jimọh ati irun yidi pade , ẹni ba fẹ  lati reti asiko jimọh lee  se  bẹẹ  ninu ẹyin ti ẹ wa lati ọna jinjin, sugbọn ẹyin ti ẹ ba fẹ  pada wa, mo yọnda fun yin” Bukhari lo yọ  Hadiisi naa jade .

Awọn Alfa se  alaye  wipe : o yẹ  ki Imam ki irun yidi fun awọn eniyan ki o si tun ki Jimọh fun wọn pẹlu, tori pe  eleyi ni yoo jẹ ki ọpọlọpọ  eniyan ni anfaani pipe .

Ti a ba ki irun tan ni ọjọ ọdun o dara ki a ki ara wa wipe : ẹ  ku ọdun, ki a se  adura fun awọn eniyan wa, awọn ara ile wa, awọn ọmọ iyaawa ati awọn ara ilu wa pẹlu: (تقبل الله منا ومنكم)   : Ọlọhun  ki ọ  gba ijọsin yii lọwọ wa ati ẹyin naa .

هذا، قال الله تعالى : "إِنَّ اللهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيْتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغِيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَرُونَ. وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللهِ إِذَا عَهَدْتُمْ وَلاَتَنْقُضُوا الْأَيْمَنَ بَعْدَ تَوْكَيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللهُ عَلَيكُمْ كَفِيلاً إِنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونٍَ"

اللَّهُمَّ أّرِنَا الْحَقَّ حَقًا، وَارْزُقْنَا اتِّبَاعَه، وَأَرِنَا الْبَاطِلَ بَاطِلاً ، وَارْزَقْنَا اجْتِنَابَه.

اللَّهُمَّ وَلِّ أُمُورَنَا خِيَارَنَا، وَلاَ تُوَلِّ أُمُورَنَا شِرَارَنَا، اللَّهُمَّ اصْلِحْ وُلاَةَ أُمُورَنَا، وَلاَ تُوَلِّ عَلَيْنَا بِذُنُوبِنَا مَنْ لاَ يَخَافُكَ فِيْنَا وَلاَ يَرْحَمُنَا. اللَّهُمَّ اغْفِرْ جَمِيعَ أَمْوَاتِ الْمُسْلِمِينَ الَّذِينَ شَهِدُوا لَكَ بِالْوَحْدَانِيَةِ وَبِنَبِيِّكَ بِالرِّسَالَةِ وَمَاتُوا عَلَى ذَلِكَ. اللَّهُمَّ اغْفِرْلَهُمْ وَارْحَمُهُمْ وَاعَفْ عَنْهَمْ وَاكْرِمْ نُزُلَهُمْ، وَوَسِّعْ مُدْخَلَهُمْ وَاغْسِلْهُمْ بِاْلَماَءِ وَالثَّلْجِ وَالْبَرَدِ، وَنَقِّهِمْ مِنَ الُّذنُوبِ وَالْخَطَايَا كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ وَارْحَمْنَا اللَّهُمَّ إِذّا صِرْنَا إِلَى مَا صَارُوا إِلَيْهِ بِرَحْمَتِكَ يَا أَرْحَمَ الرَّاحِمِينَ